Yoruba dun in ka

Oro orúko eniyan

Saturday, January 9, 2021

Èyà Ara fun ìró pipe(organs of speech)

 Kíni èyà Ara ìfò?

  Èyà Ara ìfò ní àwon èyà Ara tí a máa n lò fún pipe ÌRÓ jáde ní enu. 

    ÀWON ÈYÀ ARA ÌFÒ NÌWÒN YÌÍ:

Èdòfóró – Lungs

Eran èdòfóró – Lung muscle

Èka kòmóòkun – Bronchia tube

Kòmóòkun – Trachea/ wind pipe

Gògóngò – Voice box

Tán án ná – Vocal cord

Àlàfo tán án ná – Gloria

Káà òfun – Pharyngeal cavity

Ahón – Tongue

Èyin ahón – Back of the tongue

Àárín ahón – Middle of the tongue

Iwájú ahón – Blade of the tongue

Káà enu – Oral cavity

Òlélé – Uvula

Àfàsé – Velum/ soft palate

Àjà enu – Hard palate

Èrìgì – Alvealar 

Eyín òkè – Upper front teeth

Eyín ìsàlè – Lower teeth

Ètè ìsàlè – Lower lip

Ètè òkè – Upper lip

Káà imú – Nasal cavity

 

    ÌSÒRÍ ÈYÀ ARA ÌFÒ

A lè pín àwon èyà Ara ìfò sí ìsòrí méjì:

(1)  ÀWON ÈYÀ ARA ÌFÒ TÍ A LÈ FI OJÚ RÍ:

    Ìwònyí ni àwon èyà Ara ìfò tí a lè rí pàápàá jùlo nígbà tí a bá lo dígí tàbí nnkan mìíràn. Bí àpeere:

Imú

Àjà enu

Iwájú ahón

Àárín ahón

Èyìn ahón

Ètè òkè

Ètè ìsàlè

Eyín òkè

Eyín ìsàlè

Èrìgì òkè

Èrìgì ìsàlè

Ìta gògóngò

Òlélé

Àfàsé.

(2)  ÀWON ÈYÀ ARA ÌFÒ TÍ A KÒ LÈ FI OJÚ RÍ:

   Ìwònyí ni àwon èyà Ara ìfò tí wón wà láti ikùn wá sí inú òfun. Bí àpeere:

Èdòfóró

Èka kòmóòkun

Kòmóòkun

Tán án ná

Inú gògóngò

Káà òfun.

Tuesday, November 17, 2020

ORO AROPO ORUKO

 Òrò arópò ni àwon òrò tí a n lò dípò òrò orúko nínú gbólóhûn. Bí àpeere:

(i)   Sadé ra ìwé.   >  Ó ra ìwé.
       "O" ni òrò arópò orúko tí a lò dípò Sadé".
(ii).  Bólá àti Bímpé ti lo.   >   Wón ti lo.
         "Wón" ni òrò arópò orúko tí a lò dípò"Bólá" àti " Bímpé" .
(iii).  Ajá gbó mó àwon Olè.   >  Ó gbó mó won.
       "Ó" àti "wón" jé òrò arópò orúko. "Ó" ni a lò dípò"Ajá", a sì lo "won" dípò "àwon Olè".
       ISÉ TÍ ÒRÒ ARÓPÒ ORÚKO MÁA N  
                    NÍNÚ GBÓLÓHÙN
(i)   Òrò arópò orúko lè sisé gégé bí Olùwà,àbò àti èyán nínú gbólóhûn .

(ii)  Òrò arópò orúko máa n tóka sí enì kíní, kejì àti enìkéta nínú gbólóhûn.

(iii) Òrò arópò orúko tún máa n ní ètò tí ó máa n tóka sí iye [eyo àti òpò] nínú gbólóhûn.

Monday, June 1, 2020

Oro ise

Kíni òrò ìse?

  • Òrò ìse jé kòseémàní àti òpómúléró fún gbólóhùn.O maa n so nípa ìsèlè ti ó selè láàrín OLÙWÀ àti ÀBÒ nínú gbólóhùn.B.a: 
  •            Adémólá ògèdè (òrò ìse nínú àpeere yìí ni "jé")
  •              Bólá féràn Eja.(òrò ìse nínú àpeere yìí ni "féràn".abbl.

  •  ORÍSI ISÉ ÈDÈ YORÙBÁ

  • 1 .ÒRÒ ÌSE PÓNBÉLÉ: Èyí ni òrò ìse tí wón le dá dúró.B.a: sùn,jókòó,dìde,jeun.abbl.

  • 2.ÒRÒ ÌSE ELÉLA:jé òrò ìse tí a lè fi òrò mìíràn bò àárín òrò ìse nínú.B.a:
  • Bàjé:Kóládé ba ilèkùn jé.
  • Gbàgbó: Mo gba olórun gbó
  • Padé:Mo pa ilèkùn
  • Báwí: Bàbá omo náà .abbl.

  • 3.ÒRÒ ÌSE ALÁÌLÉLÀ: Jé èyí ti a kò lè fi òrò la òrò ìse ní àárín nínú GBÓLÓHÙN.B.a:
  •          Subú
  •           Jókòó
  •           Jéwó
  •           Jeun.abbl.

  • 4.ÒRÒ ÌSE ÀSÍNPÒ:Jé lílò ju òrò ìse kan l'o nínú GBÓLÓHÙN.B.a:
  •        Mo lo ra Eja.
  •        Mo sáré dìde.
  •         Tádé gún iyán je.abbl.
  • Òrò ìse ÀSÍNPÒ ó kéré tán,ó gbódò ní tó òrò ìse méjì.

  • 5.ÒRÒ ÌSE AGBÀBÒ: Jé òrò ìse tí ó máa n gba àbò nínú gbólóhùn.Bi àpeere:
  •          Mo ri owó.
  •          Adé ra ata.
  •          Bàbá obè.abbl.

  • 6.ÒRÒ ÌSE ALÁÌGBÀBÒ: Jé òrò ìse tí kò kìí gba àbò nínú.Bí àpeere:
  •           Bólájí ga
  •           Kíké sùn
  •           Àìná kúrú.
  •           Olùkó pupa.abbl.







Saturday, May 23, 2020

AROKO LORI OMO BORI OWO

Tí e bá fé ko àròko Lori "OMO BORÍ OWÓ",ohun àkókó ti e ni láti béèrè lówó Ara yín ni wipe, irú àròko wo ni èyí?
Léyìn tí e to mo irú àròko tí ó jé,ohun tí ó kàn ni:
"KÍKO ORÍ ÒRÒ"(topic).Ìyen ni Ori òrò ti àròko yín fé dálé l'órí.
Léyìn èyí ni ó kàn "ÌFÂÀRÀ"(introduction).
Ohun tí e ó se nibi ni síso nípa kíni OWÓ? àti kini OMO? Se àlàyé ohun tí o mò nípa àwon òrò méjì yii.Léyìn náà,so nípa ìwúlò tàbí ànfààní OWÓ àti OMO, kíni àléébù àwon méjèèjì?
Tí o bá ti se èyí,ipari tàbí ìgúnle ni ó kù.
Ní abé ìgúnle re ni wàá ti faramó èyí ti o lérò wípé ó dára.
ÀKÍYÈSÍ: èyí ti ànfààní rè bá pòju àléébù rè ni ó dára jùlo.
MO L'ÉRÒ WÍPÉ ÈYÍ YÓÒ SE Ó NÍ ÀNFÀÀNÍ.

ILANA AROKO KIKO

OHUN TÍ Ó LÈ MÚ ÀRÒKO DÁRA
1.Àròjinlè l'órí àwon orí òrò ti wón bá fún wa nínú ìdánwò wa.Ronú l'órí èyí ti o l'érò wípé yóò rorùn fún o láti ko àròko lé l'órí.

2.Àgbékalè wa gbódò bâ ìlànà Ori òrò ti a yàn láàyò mu,nítorí orísirísi àròko ni o wà.

3.Lílo orísirísi onà èdè yorùbá yóò jé kí àròko tí o fé ko ní ewà.Àwon onà èdè bíi:
-Àfiwé tààrà.
-Àfiwé elélòó
-Àkànlò èdè
-Òwe
-Àfidípò
-Ìfohùnpènìyàn.abbl.

4.Ìlo àmì èdè yorùbá

5.Kíko àwon òrò wa ni àkotó òde-òní se pàtàkì.
       
 ÌGBÉSÈ/ÀGBÉKALÈ FÚN ÀRÒKO KÍKO

(i) orí òrò (topic)

(ii)ìfâàrà (introduction)

(iii) ìpínrò (paragraphs)

(iv)ìgúnlè/ìkádìí/àsokágbá.(conclusion)

(v)gígùn àròko (the length).

Thursday, May 21, 2020

GIRAMA EDE YORUBA

ÌSÒRÍ ÒRÒ ÈDÈ YORÙBÁ
  Kíni ìsòrí òrò?
ÌSÒRÍ òrò túmò sí orísirísi  ònà tí òrò pín sín nínú èdè yorùbá.
  Orísi ìsòrí ni a pín òrò yorùbá si.Àwon ni:
-Òro orúko
-Òró arópò orúko
-Òrò arópò afarajórúko
-Òrò èyán
-Oro àpèjúwe
-Òrò ìse
-Òrò àpónlé
-Òrò atókún
-Òrò àsopò.
    Ní báyìí, e jé kí á yan nà ná è wò, ni èkún rèrè.
1.ÒRÒ ORÚKO.
   Kíni òrò orúko?
 Òrò orúko jé ohun tí a lè fi dá ènìyàn,eranko,ibìkan tàbí ohun kan mò nínú èdè yorùbá.Ni kúkúrú, òrò orúko lè jé orúko eniyan, eranko, ibìkan tàbí ohun kan.Bí àpeere:
  A.ORÚKO ÈNÌYÀN:Dàda,Táyé,Káyòdé,Àìná .abbl
B.ORÚKO ERANKO:Ajá,Àgùntàn,Ewúré,kìnìún.abbl
 D.ORÚKO IBÌKAN:Àkúré,ìbàdàn,Èkó,Lókója.abbl.
 E.ORÚKO OHÚNKAN:Ìgò,Àga,Igi,Ife.abbl
     Òrò orúko lè jé ohun tí a lè fi ojú rí.Bí àpeere:ìgò,òbe,Ife,ilé,eranko.abbl.
      Òrò orúko lè jé ohun àìfojúrí bii:aféfé,òorùn,àìsàn.abbl.
     Òrò orúko lè jé ohun tí a lè kà bíi:owó,ilé,ènìyàn,okò.abbl.
     Òrò orúko tún lè jé ohun àìseékà.Bí àpeere:iyèpè,iyò, Omi,epo,gaàrí.abbl.
          IPÒ ÒRÒ ORÚKO NÍNÚ GBÓLÓHÙN
 Nínú gbólóhùn èdè yorùbá, òrò orúko máa n wà ni:
👉 IPÒ OLÙWÀ:Ní ibèèrè gbólóhùn.
👉 IPÒ ÀBÒ: Ní ìparí gbólóhùn,ó máa n tèlé òrò ìse.
👉 IPÒ ÈYÁN:Ó máa n tèlé òrò orúko ni nínú gbólóhùn.
Àpeere òrò orúko ní ipò OLÙWÀ:
          1.Adé pa eran.
          2.Bísí se obè.
          3.Péjú mu Omi.abbl.
Àpeere òrò orúko ní ipò ÀBÒ:
          1.Bólúwátifé te ìwé.
          2.Òbo Oba n ho Ìdi.
          3.Mojísólá je Ògèdè.abbl.
Àpeere òrò orúko ní ipò ÈYÁN:
         1.Aja Ode pa Ejò.
         2.Èdè Yorùbá dùn ún kà.
        3.Obè Eja dùn púpò.abbl.(to be cont....)

Njé e ti kà nípa ÀRÒKO?


       

Wednesday, May 20, 2020

AROKO 3

ORÍSI ÈYÀ ÀRÒKO (ÌTÈSÍWÁJÚ)
6.ÀRÒKO ÀJEMÓ ÌSÍPAYÁ
    Gégé bí orúko rè,ó jé àròko tí ó gbà àròjinlè.
Lílo àwòrán inú see pàtàkì nínú irú àròko báyìí.Orí òrò ti ó jemó àròko yìí máa sábàá wáyé gégé bí àpólà tàbí eyo òrò kan.
     Nínú irú àròko báyìí,a ni láti so nípa ànfààní àti àléébù to ó wà nínú orí òrò ti wón bá fún wa.Orí òrò àròko yìí lè jé pón-na ti yóò ni ìtumò méjì tàbí méta.
    A lè ménu ba gbogbo ìtumò yìí nínú àròko wa tàbí ki a ko òrò díè le l'órí.
     ÀPEERE ORÍ ÒRÒ ÀRÒKO AJEMÓ ÀSÍPAYÁ
1.ilè
2.epo
3.ikú
4.aisan
5.omi.abbl.

7.ÀRÒKO ONÍLÉTÀ
     Àròko yìí pín sí ònà méjì:
A.létà gbèfé
B.létà àìgbèfé.
   
   LÉTÀ GBÈFÉ: Jé létà sí òbí eni,òré,àbúrò,ègbón eni tàbí enikéni tí ó bá súnmó ènìyàn.

    LÉTÀ ÀÌGBÈFÉ: Jé létà ìwâsé ti òfin wonkoko de ìlànà kíko rè.abbl.

Sunday, May 17, 2020

AROKO 2

4.ÀRÒKO ÀRÍYÀNJIYÀN
   Kíni àròko àríyànjiyàn?
 jé àròko oníhà méjì"béèni àti béèkó
(Ìhà èyí ti a faramó àti èyí ti a kò faramó).
     A gbódò sòrò l'órí egbé méjèèjì sùgbón ní ìgbèyìn,a gbódò faramó egbé kan.
A kò gbódò so ìtàn tàbí pa àló nínú irú àròko báyìí.
         ÀPEERE ORÍ ÒRÒ ÀRÒKO ÀRÍYÀNJIYÀN 
1.Enil kò ní fìlà
2.Èkó òfé àti èkó d'owó
3.Omo yá j'owó lo
4.ohun tí okùnrin lè se,obìnrin lè se jùbéè lo
5.Isé dókítà sàn ju isé olùkó lo.abbl. 

5.ÀRÒKO ONÍSÒRÒNGBÈSÌ
     Àròko yìí jé àròko oní'fòròwérò.Ó àròko tí ó dálé ìtàkùròso l'áàrín ènìyàn méjì.
Kíko orúko àwon tí ó bà sòrò nínú àròko báyìí see pàtàkì.Eyi ni yóò jé kí á lè mo ohun tí olklùkù so.B.a:
  Gàníyù:(A ó ko ohun tí ó so síwájú rè).
  Bólá:( A óò kó ohun tí òun náà ko síwájú rè).
        
ÀPEERE ORÍ ÒRÒ ÀRÒKO ONÍSÒRÒNGBÈSÌ

 1.ìjoba Alágbádá
  2.Omo beere  òsi beere
  3.Gbogbo l'omo
  4.Owó kó nìfé.abbl.

Thursday, September 12, 2019

ITESIWAJU LORI AROKO

                             ALAYE LORI ORISIRI AROKO TI O WA
1.AROKO ONIROYIN:- Eyi je aroko ti a fi n so tabi salaye nipa isele ti o sele ni isoju eniyan.
                        APEERE ORI ORO AROKO ONIROYIN
a.Ijamba oko ti o sele ni isoju mi.
b.Ayeye iranti ojo ibi mi
d.Ala buburu kan ti o d`eru ba mi
e.ojo buruku esu gbomi mu.abbl.
2              .AROKO ALAPEJUWE.
Aroko yii je eyi ti a fi n so ni pato bi nnkan se ri.
APEERE ORI ORO AROKO ALAPEJUWE
a.Ounje ti mo feran ju.
b.Ile iwe mi
d.Aburo mi
e.Oja adugbo mi
e.Ona ile oba ilu wa.abbl.
3            .AROKO ALALAYE
Eyi je aroko ti a fi n se alaye nipa nnkan.Eni ti o ba n ko aroko yii maa n wa ni ipo oluko nigba ti eni ti o n ka iru aroko yii maa n wa ni ipo akekoo,nitori pe oluko aroko yii fe se alaye nipa ohun ti a oo mo nipa re tabi ti a o mo bi a se le se sugbon ti a fe ko nipa re.
            APEERE IRU AKORI AROKO YII NI:
a.akara dindin
b.Asa ikobinrinjo ni aye atijo
d.Igba ojo
e.Bi a se nko ile ni aye atijo.abbl.(to be cont)

Tuesday, July 4, 2017

ITUMO AROKO

       AROKO KIKO
Kíni Àròko?
   Aroko tunmo si ohun ti a ro ti a si ko sile ni ona ti yoo gba ye elomiiran lati ka.

       ORISI AROKO

1.Aroko oniroyin.
2.Aroko Alapejuwe
3.Aroko Alalaye.
4.Aroko Ariyanjiyan.
5.Aroko onisorongbesi.
6.Aroko Ajemo isipaya
7.Aroko Onileta.abbl.