Yoruba dun in ka
Oro orúko eniyan
Oro ise
Kíni òrò ìse?
- Òrò ìse jé kòseémàní àti òpómúléró fún gbólóhùn.O maa n so nípa ìsèlè ti ó selè láàrín OLÙWÀ àti ÀBÒ nínú gbólóhùn.B.a:
- Adémólá jé ògèdè (òrò ìse nínú àpeere yìí ni "jé")
- Bólá féràn Eja.(òrò ìse nínú àpeere yìí ni "féràn".abbl.
- ORÍSI ISÉ ÈDÈ YORÙBÁ
- 1 .ÒRÒ ÌSE PÓNBÉLÉ: Èyí ni òrò ìse tí wón le dá dúró.B.a: sùn,jókòó,dìde,jeun.abbl.
- 2.ÒRÒ ÌSE ELÉLA:jé òrò ìse tí a lè fi òrò mìíràn bò àárín òrò ìse nínú.B.a:
- Bàjé:Kóládé ba ilèkùn jé.
- Gbàgbó: Mo gba olórun gbó
- Padé:Mo pa ilèkùn dé
- Báwí: Bàbá bá omo náà wí.abbl.
- 3.ÒRÒ ÌSE ALÁÌLÉLÀ: Jé èyí ti a kò lè fi òrò la òrò ìse ní àárín nínú GBÓLÓHÙN.B.a:
- Subú
- Jókòó
- Jéwó
- Jeun.abbl.
- 4.ÒRÒ ÌSE ÀSÍNPÒ:Jé lílò ju òrò ìse kan l'o nínú GBÓLÓHÙN.B.a:
- Mo lo ra Eja.
- Mo sáré dìde.
- Tádé gún iyán je.abbl.
- Òrò ìse ÀSÍNPÒ ó kéré tán,ó gbódò ní tó òrò ìse méjì.
- 5.ÒRÒ ÌSE AGBÀBÒ: Jé òrò ìse tí ó máa n gba àbò nínú gbólóhùn.Bi àpeere:
- Mo ri owó.
- Adé ra ata.
- Bàbá sé obè.abbl.
- 6.ÒRÒ ÌSE ALÁÌGBÀBÒ: Jé òrò ìse tí kò kìí gba àbò nínú.Bí àpeere:
- Bólájí ga
- Kíké sùn
- Àìná kúrú.
- Olùkó pupa.abbl.
No comments:
Post a Comment